Daniel Amokachi n bo nibi ayeye odun ere idaraya ti ileese Adrons gbe kale
Gbogbo eto lo ti to bi ileese Adrons Home and Properties se gbe eto ayeye odun ere idaraya ti yoo waye lojo kokandinlogun OSU kejo odun yii. Ayeye ere idaraya ati Ebun jije yii ni ileese to laami laaka nidi ise Ile tita iyen ileese Adrons Home and Properties gbe kale lati fi ro awon odolangba ati awon omode ti ojo Ori won bere lati odun mefa si odun metadinlogun lagbara
Inu Gbogan Olori Aderonke Emmanuelking to wa ni Shimawa ni ayeye yii yoo ti waye, oludasile ileese Adrons,Oloye EmmanuelKing so pe,ohun iwuri lo maa n je fun oun pelu ipa tawon ogo weere Iko yii nko ninu ere idaraya eyi lo mu oun gbe eto naa kale.
Ogbeni Daniel Amokachi to je okan ninu awon agba nidi ere boolu afesegba lorile ede yii naa ti Fidi e mule pe,oun n bo nibi ayeye naa pelu.
Tojuboleonlinenews.com.ng